JSS3 Yoruba Exam Past Questions- MOCK Free Download. Get all your educational resources with their mark guide here. All is available.
PÉPÀ 1
ÌBÉÈRÈ ÈWO-NÌ-DÁHÙN
Dáhùn gbogbo ìbéèrè tí ó wà nínú pépà yìí
ÀKÀYÉ
Ka àwo̩n àyo̩kà ìsàlè̩ wò̩nyí kí o sì dáhùn àwo̩n ìbéèrè tí ó tè̩lé ò̩kò̩ò̩kan wo̩n.
O̩mo̩ pò̩ bí o̩sàn-bó̩ ni Ayò̩kúnnú. Àké̩bàjé̩ o̩mo̩ o̩ló̩rò̩ ni. Inú owó ni àwo̩n òbí rè̩ bí i sí. Onís̩òwò nlá ni Adédo̩jà bàbá rè̩. Owó àwo̩n òbí rè̩ yìí ni kò jé̩ kí ó fojú sé̩kò̩ó̩ rè̩ tí ó fi rò pé bí òun kò tilè̩ kàwé, owó àwo̩n òbí òun tó òun I na títí do̩jó̩ alé.
Tanímòla ní tire, oúnje òsán kìí bá ti àárò nínú rè̩ s̩ùgbó̩n ó ti pinnu pé ibi tí àwo̩n òbí òun kò le dé ní rere. Òun yóò sa ipá òun láti débè̩. Gbogbo akitiyan àwo̩n òbí Ayò̩kúnnú láti rip é ó kàwé ni ó já sí pàbo. Mofé̩rere, ò̩gá àgbà ilé-è̩kó̩ wo̩n, fi orúko̩ Tanímò̩la ráns̩é̩ sí Adérò̩gbà, alás̩e̩ ètò è̩kó̩, fún ètò è̩kó̩ ò̩fé̩, Tanímò̩la sì lo ètò ò̩fé̩ yìí dé Yunifásitì.
Nígbè̩yìn, wó̩n lé Ayò̩kúnnú kúrò ní ilé è̩kó̩ nítorí àìmò̩wé rè̩. Lé̩yìn ikú àwo̩n òbí rè̩ tí àwo̩n bánkì wá gbé̩sè̩ lé gbogbo ohun ìní wo̩n ni ó tó mò̩ pé owó bánkì ni àwo̩n òbí òun n ná. Kò rów
Ó ná mó̩ torí pé kò nís̩é̩ ló̩wó̩. Èyí ni ó fà á tí ó fi di ato̩ro̩je̩ ké̩yìn ayé rè̩. Tanímò̩la ní tirè̩ gboyè agbe̩jó̩rò, ó sì di `ilú mò̩-ó̩n-ká nítorí às̩eyege tí ó máa n s̩e níwájú adájó̩.
Read Also: JSS3 History Examination Questions- Mock
- E̩ni tí ó s̩okùnfà è̩kó̩ ò̩fé̩ fún Tanímò̩la ni (a) Adérò̩gba (b)mofé̩rere (c) ayò̩kúnnú (d) Adédòjà.
- Adédo̩jà jé̩ (a) onís̩òwò nlá (b)ò̩gá àgbà ilé-è̩kó̩ (c) gbájúmò̩ agbejó̩rò (d) alás̩e̩ ètò è̩kó̩.
- Tanímò̩la ni ó di (a) ato̩ro̩je̩ nígbè̩yìn (b) alás̩e̩ ètò è̩kó̩ (c)agbe̩jó̩rò pàtàkì (d)ò̩gá àgbà ilé-è̩kó̩.
- Ta ni agbójúlógún? (a) mofé̩rere (b)adérò̩gbà (c) adédo̩jà (d) ayò̩kúnnu.
- Ìpinnu Ayò̩kúnnu nip é kí òun (a) di onís̩òwò nlá (b) di adájó̩ (c) múra sí è̩kó̩ òun (d) máa ná owó òbí òun.

Às̩à Yorùbá rewà púpò̩: ó sì jé̩ ohun ìwúrí fún gbogbo àwo̩n o̩mo̩ káàárò̩-o-òjíire láti máa gbé e láruge̩. Lára àwo̩n àmúye̩ às̩à Yorùbá ni mímo̩ èdè é lò, kí o̩mo̩ Yorùbá s̩ò̩rò̩, kí ó sì fa kòmóòkun ò̩rò̩ yo̩. Ìpèsè orís̩irís̩I oúnje̩ ilè̩ Yorùbá, s̩ís̩e ara ni ò̩só̩ àti wíwo̩ as̩o̩ tó bá òde mu: gbogbo àwo̩n ìwò̩nyí ni Yorùbá fi n yangàn láwùjo̩.
Lode òní, às̩à àjèjì ti gba gbogbo àwo̩n ohun ìs̩è̩nbáyé wò̩nyí lówó̩ púpò̩ nínú wa. Èdè Gè̩é̩sì ni púpo̩ o̩mo̩ Yorùbá n fò̩. Gbogbo as̩o̩ tó buyì ké̩wa tí ó dáàbò bo gbogbo ògo tí o̩ló̩run fún wa ti n di ohun ìgbàgbé lo̩. Ìhòòhò ni àwo̩n o̩mo̩ mìíràn n rìn kiri ìlú.
Irun dídì, bí I pàté̩wó̩, ko̩júsó̩ko̩, ìpàkó̩ e̩lé̩dè̩, sùkú, korobá àti bé̩è̩ bé̩è̩ lo̩ tí ó máa n móge re̩wà ti fe̩rè̩ di àfisé̩hìn téégún n fis̩o̩. Àsà irun jíjó, gbígbé irun àgùntàn lérí ti gbalè̩ kan láàrín ò̩pò̩ obìnrin, tí ò̩pò̩ o̩mo̩kùnrin sì n dirí bi e̩lé̩gùn S̩àngó.
- ——–kì í s̩e àmúye̩ o̩mo̩ Yorùbá (a) mimo̩ èdè é lò (b) s̩ís̩e ara ló̩s̩ò̩ó̩ (c)pípèsè oúnje̩ ìbílè̩ (d) jíjó irun níná.
- Nípasè̩ às̩à wo ni a fi so̩ Yorùbá di o̩mo̩ káàárò̩ o ójiire (a) ìmúra (b) ìkíni (c) ìpèsè óúnje̩ (d) irun dídì.
- Èwo ni ó tàbùkù às̩à ìwò̩so̩ Yorùbá? (a) síso̩ èdè Gè̩é̩sì (b) lílo wíìgì (c) irun dídì o̩kùnrin (d) rírìn ìhòhò.
- Orís̩ii irun dídì wo ni a mé̩nu bà gbè̩yìn nínú àyo̩kà yìí? (a) korobá (b) pàté̩wó̩ (c) ko̩jús ó̩ko̩ (d) sùkú.
- Àko̩lé tí ó bá àyo̩kà yìí mu jù lo̩ ni (a) àsà Yorùbá tó n kú lo̩ (b) as̩o̩ wíwò̩ lode òní (c) irun dídì ní ilè̩ Yorùbá (d) ojúse o̩mo̩ Yorùbá àtàtà.
- . “ Ò̩gá ilé è̩kó̩ mi” lè jé̩ orí ò̩rò̩ fún àròko̩ (a) asàpèjúwe (b) asò̩tàn (c) asàríyànjiyàn (d) aje̩mó̩ ìs̩ípayá.
- Orí ò̩rò̩ wo ló je̩ mo̩ àròko̩ asò̩tàn jù? (a) igi ò̩pe̩ (b) ìdíje bóòlù kan tí mo wò (c) owó ju o̩mo̩ lo̩ (d)ò̩gá ìlú mi.
- “ Bí mob á di ò̩gá àgbà ilé-è̩kó̩ mi lè jé̩ orí ò̩rò̩ fún àròko̩ (a) as̩àpèjúwe (b) as̩àríyànjiyàn (c) asò̩tàn (d) aje̩mó̩ ìs̩ípayá.
- Kí a tó bè̩rè̩ àròko̩ ní kíko̩ a gbó̩dò̩ s̩e (a) ìkíni (b) ìfáàrà (c) àmúlò èdè (d) ìlapa èrò.
- Ìró àkùnyùn ni (a) [t] (b) [f] (c) [g] (d) [k].
- “ Aré̩gbé̩s̩oyè” jé̩ ò̩rò̩ onísílébù (a) mé̩rin (b) márùn-ún (c) mé̩fà (d) méje.
- Àpe̩e̩re̩ àfipè àsúnsí (a) eyín òkè (b)ètè òkè (c) ìwájú ahó̩n (d) àjà e̩nu.
- Nínú ìhun sílébù èdè Yorùbá. ‘f’ nínú “alángbá” ni (a) a (b) lá (c)n (d) gbá.
- “ Dáradára” di ‘dáadáa’ nípasè̩ (a) ìkànpò̩ (b) ìpaje̩ (c)àrànmó̩ (d)ìyó̩pò̩.
- Èwo ni ò̩rò̩ àyálò àfojúyá? (a) pítà (b) só̩jà (c) tébù (d)pásító̩.
- Ató̩ka ìsè̩lè̩ bárakú ni (a) yóò (b) á (c) tí (d) máa n.
- “Olú ni ó pa ò̩yà” jé̩ àpe̩e̩re̩ gbólóhùn (a) àkíyèsí aláte̩numó̩ (b) alákànpò̩ (c) as̩àpó̩nlé (d) abó̩dé.
- “ Kó” jé̩ ató̩ka gbólóhùn (a) ìyísódì (b) àkíyèsí aláte̩numó̩ (c) ìbéèrè (d) alákànpò̩.
- Èwo ló ní ibá ìs̩è̩lè̩ às̩etán nínú? (a) èmi yóò lo̩ (b) bó̩lá n je̩un ló̩wó̩ (c) mo ti yó (d) mo máa ka ìwé.
- Nínú “òun ni ó fó̩ o̩pó̩n o̩ba” ò̩rò̩ aró̩pò afarajórúko̩ ni (a) o̩ba (b) ó (c) o̩pó̩n (d) òun.
- Irúfé̩ ò̩rò̩-ìs̩e wo ló wà nínú “ So̩lá ba àga náà jé̩”? (a) ò̩rò̩-ìs̩e e̩lé̩là (b) ò̩rò̩-ìs̩e àkànmórúko̩ (c) ò̩rò̩-ìs̩e aláìlé̩là (d) ò̩rò̩-ìs̩e alápèpadà.
Túmò̩ ò̩kò̩ò̩kan gbólóhùn tí ó wà ní ìbéèrè̩ 27-30 sí ojúlówó èdè Yorùbá.
- He was ashamed of his action (a) ohun tí ó s̩e tì í lójú (b) ó kábàámò̩ `iwà rè̩ (c) ó fìka bo̩nu lórí ohun tí ó s̩e (d) wó̩n dójú tì í torí ìwà rè̩.
- It rained cats and dogs yesterday (a) òjò rò̩ díè̩ lánàá (b) òjò tó rò̩ lánàá fé̩rè̩ hú òkú ò̩le̩ (c) òjò ti fé̩è̩ rò̩ lánàá (d) òjò àná pa ò̩pò̩lo̩pò̩ ológbò àti ajá.
- Do not wash your dirty linen in public.(a) fo̩ as̩o̩ ìdó̩tí rè̩ ní kò̩rò̩ (b) más̩e tú às̩írí ara re̩ ní ìta (c) más̩e jà ní ìta (d) so̩ ò̩rò̩ e̩nu re̩ ní kò̩rò̩.
- He that has ears let him hear. (a) e̩ni tí ó bá ni etí kí ó gbó̩ (b) e̩ni tí kò ní etí kò lè gbó̩ràn (c) àìgbó̩ràn kò lérè (d) àfojúdí ni àìgbó̩ràn.
LÍTÍRÉS̩O̩
- S̩ágo n búgò” je̩ àpe̩e̩re̩ (a) àkànlò èdè (b) àfiwé tààrà (c) àwítúnwí (d) ìfohùndárà.
- “ wó̩n fi ilé po̩ntí, wó̩n fò̩nà rokà, wó̩n fi gbogbo agbada dínran” jé̩ àpe̩e̩re̩ (a) ìfohùnpènìyàn (b) àso̩régèé (c)àdàpè (d) àfiwé.
- Ò̩nà ìs̩o̩wó̩lo-èdè wo ló wà nínú àgbékalè̩ “ ikú pa Abírí, Abírí kú, ikú pa Abìrì, Abìrì rò̩run”? (a) àdàpè (b) è̩dà ò̩rò̩ (c)dídó̩gba (d) àfidípò.
- Èwo ni a lè fi dípò “ àkàrà tú sépo” (a) ilé̩è̩ gbé (b) o̩jó̩ pofírí (c) awó ya (d) inú konú.
LÍTÍRÉS̩O̩ ALOHÙN
- Ta ni wó̩n tàn je̩ (a) e̩kùn (b) ìjàpá (c) adìé̩ (d) kò̩lò̩kò̩lò̩.
- Ta ni ó gba adìe̩ lówó̩ kò̩lò̩kò̩lò̩? (a) àkùko̩ (b) kìnìún (c) ìkookò (d)àgbè̩
- Ìtàn yìí kó̩ wa pé kí a (a)sá fún ò̩tá wa (b) tú às̩írí ò̩ré̩ wa (c) kí a so̩ra fún ò̩ré̩ (d) kí a s̩ó̩ è̩hìnkùlé wa.
EWÌ
- Ìran wo ni a tún n pè ní Òkò? (a) olúpo (b) ajíso̩lá (c) ajíbógundé (d) olówu.
- Kí ni orúko̩ baba-nlá ìra ajíbógundé (a) Okoye (b) òsé (c) Ajíbógundé (d) kúje̩mirá.
- Is̩é̩ tí a mó̩ mo̩ ìran yìí ni (a) ò̩nà yíyè̩ (b) ogun jíjà (c) ère gbígbé̩ (d) e̩rú rírà.
ÈGÈ DÍDÁ
- Ní àárò̩ o̩jó̩, àwo̩n wo ló ni ègè dídá? (a) olórò (b) onísàngó (c) elésù (d) onífá.
- Wo̩n n dá ègè ní ilè̩ (a) ò̩yó̩ (b) èkìtì (c) è̩gbá (d) ìjè̩bú.
- Os̩ù kélòó nínú o̩dún ni wó̩n máa n s̩e o̩dún orò? (a) karùn-ún (b) ke̩fà (c) ke̩jo̩ (d) ke̩sàn-án.
LÍTÍRÉS̩Ò̩ ÀPILÈ̩KO̩
- Bàbá o̩ko̩ olúrónbí (a) jé̩ ò̩kan nínú àwo̩n olóyè (b) n bo ilé rè̩ tó s̩è̩s̩è̩ mo̩ tán (c) gbé o̩mo̩ lo̩ sí oko (d) kó marìwò ò̩pe̩ bora.
- ————–ni ó n fi è̩mí àwo̩n ènìyàn sÒfò (a) àrólé oòdua (b) àwo̩n ùgbò (c) atè̩wo̩nrò̩ (d) o̩rúntó̩.
- E̩ni tí ó gbó̩fá yanranyanran ni (a) Diwúrà (b) Elíjo̩ba (c) ìyá Mó̩rémí (d) o̩ko̩ ol’urónbí.
- Nínú ewì “ ò̩rò̩ e̩nu akéwì” kí ni akéwì pe ò̩rò̩ e̩nu ògìdán? (a) kowéè kowéè (b)igbe rara (c) bíbú ramúramù (d) yíyo̩ iná lé̩nu.
- Kí ni bàbá àgbè̩ rò̩gbò̩kú lé lórí? (a) tanmo̩sóko (b) òjò tí ó kù (c) o̩lá bàbá (d) kádàrá.
- Akéwì so̩ pé aké̩kò̩ó̩ kò gbo̩dò̩ rò̩gbò̩kú lé (a) o̩lá bàbá (b) po̩nmipo̩nmi (c) is̩é ìjo̩ba (d) is̩é̩ gbé̩nàgbé̩nà.
ERÉ ONÍTÀN
- Àláájà fé̩ gba Oyèládùn s̩ílé nítorí pé (a) kò ní o̩mo̩ tí ó lè máa bá a gbé ilé (b) ó nílò o̩mo̩ tí yóò máa s̩is̩é̩ inú ilé (c) ó fé̩é̩ rán an ní ilé-è̩kó̩ (d) ó jé̩ ò̩ré̩ Àbè̩ní.
- Éèlòó ni Oyèládùn ta míìlìkì? (a) àádò̩ta náírà (b) e̩gbè̩rún méjì (c) è̩é̩dé̩gbè̩ta náírà (d) o̩gó̩fà náirà.
- Báyò̩ ni (a) o̩mo̩ Àdìó (b) o̩mo̩-ò̩dò̩ Àbè̩ní (c) o̩mo̩ ò̩dò̩ O̩ládè̩jo̩ (d) o̩mo̩ Àdíjà.
ÀSÀ
- È̩mú jé̩ ò̩kan lára irinsé̩ (a) alágbè̩de̩ (b) ape̩ja (c) ahunso̩ (d) akò̩pè̩.
- Èwo ni ìgbésè̩ àkó̩kó̩ nínú ètò ìgbéyàwó? (a) ìdána (b) ìto̩ro̩ (c) ìjó̩hen (d) ìfojúsóde.
- Òrìs̩à wo ni kì í mu e̩mu ? (a) orò (b) ò̩bàtálá (c) s̩àngó (d) ògún.
- Èwo ni a kì í fi erèé s̩e ? (a) mó̩ínmó̩in (b) àkàrà (c) àádùn (d) gbè̩gìrì.
- Ta ni à n kí ní “àredú o” tí a bá bá a lé̩nu is̩é̩? (a) o̩de̩ (b) àgbè̩ (c) aláró (d) onídìrí.
- Èwo ni ó je̩ mó̩ ìtó̩jú o̩mo̩ o̩wó̩? (a) are̩mo̩ (b) ìgbè̩bí (c) abíwé̩ré̩ (d) ìde oyún.
- Èwo ni kò bé̩gbé̩ mu nínú àwo̩n wò̩nyí? (a) ilé mos̩ú (b) ìyálé (c) o̩mo̩bìnrin ilé (d) ìyàwó ilé.
- Is̩é̩ abínibí ìran Arè̩sà ni (a) igbá fínfín (b) epo fífò̩ (c) ogun jíjà (d) adé sínsín.
PÉPÀ II
- ko̩ àròko̩ tí kò dín ní ò̩ó̩dúnrín (300) è̩yo̩ ò̩rò̩ lórí orí-ò̩rò̩ kan s̩os̩o tí ó bá yàn. Más̩e lò ju ìs̩é̩jú márùndínláàádó̩ta lórí abala yìí. Èdè Yorùbá ni kí o fi dáhùn gbogbo ìbéèrè kí o sì lo àko̩to̩ òde-òní àti èdè-ìperí Yorùbá.
- O̩gá ilè is̩é̩ mi (b) È̩kó̩ ò̩fé̩ kò dára (c) Igi owó (d) Ìs̩è̩lè̩ láabi kan tó soju mi (e) Ko̩ lé̩tà sí ò̩ré̩ re̩ tí ó wà ní ìlú òdìkejì kí ó sì s̩àlàyé fún un ìpò tí ìlú re wà ló̩wó̩ló̩wó̩.
Dáhùn ìbéèrè kan soso níhìn-ín
2 (a) kí ni fóònù
(b) kí ni fóníìmù?
(d) S̩e àdàko̩ àwo̩n lé̩ta wò̩nyí ní ìlànà fóníìmù
(i) s̩ (ii) o̩ (iii) e̩ (iv) j (v) gb (vi) un (vii) y; (viii) p (ix) in (x) l
- To̩ka sí àwo̩n ò̩rò̩ tí ìpàje̩ wà nínú ìs̩è̩dá wo̩n nínú àyo̩kà ìsàlè̩ yìí kí o sì so̩ ìró tí a paje̩ nínú ò̩kò̩ò̩kàn wo̩n.
Mo̩yò̩só̩re̩ kúrò ní ojúde o̩ba, ó gba ò̩nà ilé rè̩ ló̩ sí ìdíkò̩. Lójú ò̩nà, ó rí àwo̩n tí ó n jè̩sé̩ ní etídò. Ti pé ó wo̩so funfun tí ó sì tún fé̩ ya ò̩dò̩ ìyako̩ rè̩ kó tilè̩ wo ibè̩ rárá. Ó yà kò̩wé sílè̩ fún àbúrò rè̩.
GÍRÁMÀ
Dáhùn ìbéèrè kan s̩os̩o níhìn-ín
4̩. So̩ ìsò̩rí ò̩rò̩ tí àwo̩n ò̩rò̩ kò̩ò̩kan tí a falà sí nídìí nínú gbólóhùn wò̩nyí wà.
- Wàhálà Olú pò̩ .
- MOpàtàkì ara mi
- Má wàhálà
- Àwo̩ntí à n retí ti dé.
- O̩mo̩ wù mí.
- Bólá Ìbàdànga ju Bó̩lá Èkó lo̩
- As̩o̩ pupani Olú wò̩.
- È̩bùn wà níinú mó̩tò.
- Ó s̩e isu s̩ùgbó̩nkò je̩ é̩.
- Ilé wani Bísí n gbé.
5(a) Dárúko̩ márùn-ún nínú orís̩irís̩I èyán tí ó wà nínú àpólà orúko̩.
(b) Fi àpe̩e̩re̩ kò̩ò̩kan kín ìdáhùn re̩ ní 5(a) lé̩yìn.
(d) lo àpe̩e̩re̩ kò̩ò̩kan ní 5(b) nínú gbólóhùn.
ÌPÍN B LÍTÍRÉS̩O̩ : DÁHÙN ÌBÉÈRÈ MÉJÌ PÉRÉ NÍNÚ ÌPÍN YÌÍ
LÍTÍRÉS̩O̩ ALOHÙN: DÁHÙN ÌBÉÈRÈ KAN S̩OS̩O NÍHÌN-ÍN
ÌTÀN ÀRÒSO̩
- Nínú ìtàn “ìjàpá àti Àkèré” báwo ni ayò̩ àyò̩jù s̩e jé̩ kí àkèré sé̩ ní itan?
EWÌ
- Nínú oríkì “Ìran ajíbógundé” s̩àlàyé bí abímbés̩ù s̩e jogun ìran òpó.
ERÉ-ONÍSE
- Mé̩nu ba àwo̩n ohun tí ègè dídá máa n dá lé lórí.
LÍTÍRÉS̩O̩ ÀPILÈ̩KO̩
DÁHÙN ÌBÉÈRÈ KAN S̩OS̩O NÍHÌN-ÍN
- Ró̩ ìtàn bí wó̩n s̩e rí òkú Olúrónbí ní oko e̩gàn.
EWÌ
- So̩ àwo̩n ìpalára tí akéwì so̩ pé màgòmágó ìdánwò n fà gé̩gé̩ bí ó ti je̩ yo̩ nínú ewì “ màgòmágó ìdánwò”.
ERÉ ONÍTÀN
11.Ròyìn bí aye̩ye̩ ìsìnkú bàbá àgbà s̩e lo̩ lóko.
ÌPÍN D: ÀS̩À
- Ò̩nà wo ni à n gbà kí àwo̩n wò̩nyí?
(a) Àgbàlagbà (b) E̩ni tí ó dúró (d) Àwo̩n tí ó n s̩e ìpàdé ló̩wó̩. (e) E̩ni tí ó jókòó (e̩) E̩ni tí ó fé̩é̩ wo̩lé
( f) E̩ni tí ó s̩ès̩è̩ bímo̩ ( g) E̩ni tí ó lóyún sínú ( gb) E̩ni tí ìjànbá s̩e̩lè̩ sí (h ) E̩ni tí ó pè wá láti wá je̩un
( i) E̩ni tí ó wà ní ipò o̩lá
- S̩àlàyé lé̩kùn-ún ré̩ré̩ lórí bí a s̩e n sìnkú e̩ni tí àrá sán pa.
—————————————————————————————————————————————— 
ÌPÍN B LÍTÍRÉS̩O̩ : DÁHÙN ÌBÉÈRÈ MÉJÌ PÉRÉ NÍNÚ ÌPÍN YÌÍ
LÍTÍRÉS̩O̩ ALOHÙN: DÁHÙN ÌBÉÈRÈ KAN S̩OS̩O NÍHÌN-ÍN
ÌTÀN ÀRÒSO̩
- Nínú ìtàn “ìjàpá àti Àkèré” báwo ni ayò̩ àyò̩jù s̩e jé̩ kí àkèré sé̩ ní itan?
EWÌ
- Nínú oríkì “Ìran ajíbógundé” s̩àlàyé bí abímbés̩ù s̩e jogun ìran òpó.
ERÉ-ONÍSE
- Mé̩nu ba àwo̩n ohun tí ègè dídá máa n dá lé lórí.
LÍTÍRÉS̩O̩ ÀPILÈ̩KO̩
DÁHÙN ÌBÉÈRÈ KAN S̩OS̩O NÍHÌN-ÍN
- Ró̩ ìtàn bí wó̩n s̩e rí òkú Olúrónbí ní oko e̩gàn.
EWÌ
- So̩ àwo̩n ìpalára tí akéwì so̩ pé màgòmágó ìdánwò n fà gé̩gé̩ bí ó ti je̩ yo̩ nínú ewì “ màgòmágó ìdánwò”.
ERÉ ONÍTÀN
11.Ròyìn bí aye̩ye̩ ìsìnkú bàbá àgbà s̩e lo̩ lóko.
ÌPÍN D: ÀS̩À
- Ò̩nà wo ni à n gbà kí àwo̩n wò̩nyí?
(a) Àgbàlagbà (b) E̩ni tí ó dúró (d) Àwo̩n tí ó n s̩e ìpàdé ló̩wó̩. (e) E̩ni tí ó jókòó (e̩) E̩ni tí ó fé̩é̩ wo̩lé
( f) E̩ni tí ó s̩ès̩è̩ bímo̩ ( g) E̩ni tí ó lóyún sínú ( gb) E̩ni tí ìjànbá s̩e̩lè̩ sí (h ) E̩ni tí ó pè wá láti wá je̩un
( i) E̩ni tí ó wà ní ipò o̩lá
- S̩àlàyé lé̩kùn-ún ré̩ré̩ lórí bí a s̩e n sìnkú e̩ni tí àrá sán pa.